Filtrer par genre
- 23 - Leta Aigbefe V2
LETA AIGBEFE
Leta kiko je ona ti a n gba ranse asiri si ara eni. Ninu leta kiko ni a ti maa n ni anfaani julo lati fi ero ara wa han lori ohunkohun. Yala si ore wa, obi wa, ibatan wa, awon oniwe iroyin, oga ile iwe, ijoba, oga ile ise abbl.
Ni kukuru LETA AIGBEFE ni leta ti ko gba efe rara. Eyi ni leta ti a n ko lati wa ise, tabi si ijoba, , ajo gbogbo laarin ilu tabi lawujo tabi nigba ti a ba ni nkan gba lowo awon olu ile ise.
Ewe, a tun le ko irufe leta bayi si
- Olootu iwe iroyin - Oga ile iwe - Giwa ile ise abbl.Igbese inu LETA AIGBEFE
- - Adiresi eni ti o n ko leta - Deeti - Ipo ati adiresi eni ti a n ko leta si - Ikini ibere - Ori oro/Anole - Inu leta -Ikini ipari ati Oruko eni ti o ko leta pelu ifowosi
Apeere KIKO AIGBEFE
2 Oluwaseyi Street, Bariga Lagos.
2nd June 2021.
Oga Ile Iwe,
Muslim Junior College,
No 13 Alaafia Street,
Oworonshoki,
Lagos.
Sa,
Itoro aye lati lo fun Odun Ibile
Mo fi asiko yi toro aaye lati lo si ilu mi fun ayeye odun egungun ti a maa n se lodoodun.
Inu mi a dun bi e ba le gbami laaaye lati kopa ninu odun yii gege bi asa mi lodoodun.
Emi ni tiyin
Rafiu Ajani.
Mon, 31 May 2021 - 12min - 22 - ORISIRI ORUKO ILE YORUBATue, 12 Jan 2021 - 11min
- 21 - Ise isenbaye ile YorubaTue, 12 Jan 2021 - 18min
- 20 - IGBAGBO AWON YORUBA NIPA ORISATue, 12 Jan 2021 - 04min
- 19 - GHOLOHUN OLOPO ORO ISETue, 12 Jan 2021 - 06min
- 18 - AROKO ASAPEJUWETue, 12 Jan 2021 - 06min
- 17 - EWI ALOHUNTue, 12 Jan 2021 - 07min
- 16 - EKA EDETue, 12 Jan 2021 - 09min
- 15 - ASA ISOMOLORUKO NI ILE YORUBAWed, 15 Jul 2020 - 08min
- 14 - OJUSE OMOLUABI SI IJOBATue, 14 Jul 2020 - 10min
- 13 - OJUSE OMOLUABI SI OBI ATI ENIKEJISun, 12 Jul 2020 - 18min
- 12 - EYA GBOLOHUN AFARAHESun, 12 Jul 2020 - 25min
- 11 - IWA OMOLUWABI ATI BI A SE LE DA OMOLUWABI MO LAWUJO
Koko Ise:
Iwa Omoluwabi ati bi a se le da Omoluwabi mo lawujo
Omoluwabi ni eni ti o fi iwa bibi ire han yala nipa eko ile tabi iwa ati ise re si enikeji.
Bi a se le da omoluwabi eniyan mo.Omoluwabi gbodo:
-ni iwa iteriba ati igbowofagba
-ni emi irele
-ni itelorun, omoluwabi kii se ojukokoro.
-omoluwabi gbodo ko ara re ni ijanu ki o to so tabi se ohunkohun.
-ni emi igboran
-je olooto ati olododo
-ni emi suuru
-tepa mose lai se ole
-je eni ti o se gbekele, ti a le fi okan tan ni igba gbogbo.
-omoluwabi kii se ilara tabi jowu enikeji
-ni ife enikeji gege bi ara re.
-ni iwa imototo ni igba gbogbo.
-omoluwabi gbodo jina si awon iwa buburu bii ija, agbeere, igberaga, imele, ofofo, ole jija, ibinu abbl.
-gbodo wo aso ti o bo asiri ara nigba gbogbo.
-omoluwabi kii huwa ika
-omoluwabi gbodo pa ogo obinrin mo saaju igbeyawo.
Sat, 11 Jul 2020 - 15min - 10 - ASA OYUN NINI, ITOJU OYUN ATI IBIMO NI ILE YORUBA
Koko Ise
Asa oyun nini, Itoju oyun ati Ibimo ni ile Yoruba:
Ni ile Yoruba, nnkan ayo ni fun ebi oko ati ebi iyawo ti iyawo ba tete loyun.
Orisirisi ona ni Yoruba maa n gba se itoju oyun ni aye atijo.
Lara won ni:
- Oyun dide
- Itoju alaboyun ati omo inu re
- Iwe awebi
Ati bee bee lo.
Alaye lekunrere ni o wa ninu fonran.
Fri, 10 Jul 2020 - 09min - 9 - ISE ORO ISE NINU GBOLOHUN
Koko Ise: Ise oro Ise ninu gbolohun
Oro Ise ni emi gbolohun. Ohun kan naa ni opomulero to n toka isele inu gbolohun. Bi apeere:
-Dupe 'pon' omi.
Sade 'ra' bata.
Olu n 'ro' amala ni ori ina.
Ti a ba yo oro ise: pon, ra, ro kuro ninu awon gbolohun oke wonyi, ko lee ni itumo.
Ise Oro Ise:Oro Ise ni o maa n toka isele inu gbolohun. Eyi ni ohun ti oluwa se. Awon oro naa la fi sinu awon nisale yii.
- Sola (pon) omi.
- Dare (ko) ile.
- Jide (ge) igi.
- Iyabo (ka) iwe.
-Funmi (be) isu.
Ati bee bee lo.
Oro Ise le sise gege bi odindi gbolohun ki o si gbe oye oro wa jade
Bi apeere :
Jade.
Jeun.
Sun.
Sare. Ati bee bee lo.
A le lo oro ise lati pase iyisodi fun eniyan nipa lilo "ma" saaju ninu ihun gbolohun
Bi apeere "
Ma sun.
Ma sare. Ati bee bee lo.
A n fi oro ise se ibeere nipa lilo wunre asebeere: da, nko ati bee bee lo.
Bi apeere:
Titi da?
Tope nko?
Thu, 09 Jul 2020 - 09min - 8 - ASA IRANRA-ENI-LOWO
Koko Ise : Asa Iranra-eni-lowo: Asa Iranra-eni-lowo je asa ti o gbajumo laarin awon Yoruba ni aye atijo.
Asa Iranra-eni-lowo yii mu ki ise ti o le gbani ni akoko pupo, di sise ni kia, ati wi pe o mu ki wahahala din ku laaarin awon eniyan ti won n gbe ni agbegbe kan naa. Bi apeere: ise oko, ile kiko, owo yiya ati bee bee lo.
Orisi ona ti a n gba ran ara wa lowo
(1) Aaaro
(2) Owe
(3) Esusu
(4) Ajo
(5) Owo eke kiko/Sogun-dogoji
(6) San-die-die
(7) Fifi omo/nnkan ini duro
Wed, 08 Jul 2020 - 14min - 7 - LETA AIGBEFE
Koko Ise: Leta Aigbefe
Leta Aigbefe ni leta ti a maa n ko, nigba ti a ba n wa ise tabi ti a ba ni nnkan gba lowo awon oga olu ile-ise kan tabi omiran.
Aye ko si fun wa lati da apara tabi se efe kankan nigba ti a ba n ko irufe leta yii.
Awon ti a maa n ko leta wonyi si ni:
1. Ile-ise ijoba bi apeere: Ile-ise eto eko.
2. Ile-ise amohun-maworan.
3. Ile-ise itewe.
4. Yunifasiti tabi ile-iwe giga miiran.
5. Ajo W.A.E.C, N.E.P.A, Water corporation ati bee bee lo.
Ki a to le se aseyori ninu kiko leta aigbefe, a ni lati tele awon igbese wonyi.
Igbese Inu Leta Aigbefe
1. Adiresi eni ti o n ko leta: Apa otun, ni oke ni adiresi eni ti o n ko leta maa n wa.
2. Deeti: Ojo ti a ba ko leta se pataki fun iranti lojo iwaju. Isale adiresi ni eyi nilati wa, a si gbodo ko o ni kikun. Bi apeere:
10th May, 2020;
29th June, 2020;
tabi: 10-05-2020;
29-06-2020.
3. Ipo ati adiresi eni ti a ko leta si: Owo osi oke leta ni a o ko ipo ati adiresi eni ti a n ko leta naa si, ila to tele ila ti a ko deeti si ni eyi yoo wa.
4. Ibere leta: Bere leta re ni owo osi pelu: Alaga, Alagba, Olootu, Oga mi Owon, Kabiyesi ati bee bee lo.
AKIYESI
Ko si ikini leyin oro-ibere leta aigbagbefe. A ko gbodo wi pe "Se alaafia ni o wa".
5. Ori oro tabi Akole leta: A ni lati fun leta aigbefe ni ori-oro ti o ba koko ero inu leta naa mu regiregi.
6. Inu leta: Ori ohun ti a fe so gan-an ni a gbodo lo taara. A ko gbodo da apara kan-kan bee ni a ko gbodo se awawi asan bi a se so saaju.
7. Ipari leta: "Emi ni tiyin" ni a gbodo fi pari leta aigbefe.
8. Oruko eni ti o ko leta: Isale gbolohun idagbere ti a fi pari leta wa ni oruko eni ti o ko leta gbodo wa. A ni lati ko oruko wa ati ti baba wa. Dandan ni ki a fihan boya okunrin ni wa tabi obinrin.
Bi apeere: Femi Adelaja (Mr), Joke Raheem (Miss).
Tue, 07 Jul 2020 - 12min - 6 - AKOTO EDE YORUBA
Akoto Ede Yoruba
(Sise Itokasi ipinu ijoba apapo ti odun 1974)
Lai fi akoko sofo, e je ka sare wo ohun ti Akoto je
Akoto ni eko nipa bi a se n ko sipeli ede Yoruba sile ni ode oni.
Leyin akitiyan awon oyinbo alawo funfun ati ijo CMS lati ri i daju wi pe ede Yoruba di kilo sile, awon onimo ede Yoruba ati ijoba iwo-oorun Naijiria leyin ominira se agbekale igbimo lorisirisi lati wa ona abayo si awon isoro kookan ti o n koju bi a se n ko sipeli ede Yoruba sile.
Bi apeere:
Aiya -Aya
Eiye - Eye
Aiye - Aye
Okonrin - Okunrin
Obiri - Obinrin
Fun u - Fun un
Yio - Yoo
Ati bee bee lo.
Mon, 06 Jul 2020 - 18min - 5 - YORUBA AJUMOLO
Koko Ise wa taaro yi ni
Yoruba Ajumolo
Yoruba Ajumolo ni ede Yoruba gbogboogbo ti a n so kaakiri ile kaaro_o_jiire.
Oun ni ojulowo ede Yoruba ti o je itewogba jakejado ile Yoruba.
Eka ede Oyo ni o sunmo ede Yoruba ajumolo pekipeki.
A gba a gege bi ede ajumolo nitori pe gbogbo eya Yoruba lo gbo o ni agboye, won si lee so o ni asoye abbl.
Sun, 05 Jul 2020 - 10min - 4 - AKANLO EDE
Koko ise wa toni ni Akanlo Ede
Eyi ni ipede ti o kun fun ijinle oro, ti itumo re farasin pupo.
Isoro ni soki soki ni akanlo ede, o si tun wulo pupo nigba ti a ba fe pe oro so.
Bi apeere, Yoruba kii wi pe ''oba ku" bikose pe oba waja.
"Igbonse" ni a maa n lo dipo igbe.
"Mo fe se eyo" dipo mo fe to. Ati bee bee lo.
Sat, 04 Jul 2020 - 21min - 3 - IGBEYAWO AYE ODE ONIFri, 03 Jul 2020 - 16min
- 2 - EYA GBOLOHUN EDE YORUBA NIPA IHUNThu, 02 Jul 2020 - 07min
- 1 - ETO IGBEYAWO ABINIBIWed, 01 Jul 2020 - 15min
Podcasts similaires à Yoruba Educational Series
- Global News Podcast BBC World Service
- El Partidazo de COPE COPE
- Herrera en COPE COPE
- Tiempo de Juego COPE
- The Dan Bongino Show Cumulus Podcast Network | Dan Bongino
- Es la Mañana de Federico esRadio
- La Noche de Dieter esRadio
- Hondelatte Raconte - Christophe Hondelatte Europe 1
- Affaires sensibles France Inter
- La rosa de los vientos OndaCero
- Más de uno OndaCero
- La Zanzara Radio 24
- Les Grosses Têtes RTL
- L'Heure Du Crime RTL
- El Larguero SER Podcast
- Nadie Sabe Nada SER Podcast
- SER Historia SER Podcast
- Todo Concostrina SER Podcast
- 安住紳一郎の日曜天国 TBS RADIO
- TED Talks Daily TED
- The Tucker Carlson Show Tucker Carlson Network
- 辛坊治郎 ズーム そこまで言うか! ニッポン放送
- 飯田浩司のOK! Cozy up! Podcast ニッポン放送
- 武田鉄矢・今朝の三枚おろし 文化放送PodcastQR